Èdè Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ogún, ọnà ìdánimọ̀ tí kò le è parun
Abstract
Èdè ni Olódùmarè fi sààmì ẹ̀dá àti ẹ̀yà tí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan jẹ́. Láìsí èdè, kò lè sí ẹ̀dá, láìsí ẹ̀dá kò lè sí Àwùjọ. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni àwọn onímọ̀ ti ṣe lórí èdè Yorùbá tí yóò fi máa gbòòrò sí i, tí kò sì ní í parun. Ọ̀nà ìparun ni èdè Yorùbá wà báyìí, pẹ̀lú ọwọ́ tí àwọn elédè yìí fi mún ún àti àwọn adarí tí a lè pè ní ìjọba àti liana tí wọ́n ṣàmúlò. Pépà yìí gbìyànjú láti wo ìhà tí àwọn ọmọ Yorùbá kọ sí èdè yìí lóde òní. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sàmúlò rẹ̀ sákálá láì kà á kún ogún pàtàkì. A ṣe ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nu-wò pẹ̀lú àwọn ènìyàn àwùjọ láti mọ ibi tí èdè Yorùbá ń doríkọ báyìí. Ó hàn gbangba pé àwọn ọ̀nà pàtàkì tí a lè gbà láti rí i pé, èdè Yorùbá kò parun ni a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú pépà yìí. A fẹ́ kí àwọn ènìyàn rí i pé èdè kò ju èdè lọ àti pé bí a bá ṣe gbé èdè wa ni àwọn ẹ̀yà mìíràn yóò ṣe bá wa gbé e. Ohun tí a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú iṣẹ́ yìí ni pé, ìjọba gbọdọ̀ jẹ́ kí èdè abínibí, pàápàá èdè Yorùbá jẹ́ ohun tí a gbọdọ̀ máa sàmúlò lóòrè-kóòrè, gẹ́gẹ́ bí èdè ọ́fíìsì, èdè gbẹ̀fẹ́ àti àìgbẹ̀fẹ́, èyí tí ó lè mú èdè kí èdè náà wà ní ipò tí èdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé àti àwọn èdè tí wọ́n ń lò káàkiri àgbáyé.